









|
|
This page will feature Yoruba stories, Poems, Wise Sayings, Yoruba
National items, as well as Editor's comments and favorite websites.
- ISE NI OGUN ISE (Work is the antidote
of Poverty)
- Ise ni ogun ise, mura si ise ọre
mi
- Isę ni afi ndi ęni giga
- Bi ako ba ri ęni fęyin ti,
- Bi ọle ni a a ri;
- Bi a ko ba ri eni gbęke le,
- A tęra mọ isę ęni.
- Iya re le lowo lọwọ,
- Ki baba re sin ni ęsin ni eekan
- Bi oba gboju le won; O te tan ni mo wi fun
o!
- Ohun ti a ko ba jiya fun,
- Ki i pe lowo rara
- Ohun ti aba f'ara sise fun ni pe lowo eni
- Apa lara, igbunpa ni iyekan
- Bi aye nfe o lonii, Bi o ba lowo lowo;
- Ni won maa fe o lola;
- Tabi ki o wa ni ipo atata,
- Aye a ye o si terin terin;
- Je ki o di eni ti n rago
- Aye a maa sa fun e!
- Eko si tun n so nii di oga,
- Mura ki o ko o daradara.
- Bi O si ri opo eniyan, ti nfi eko serin rin
- Sora ki O ma fara we wọn
- Nitori iya nbo fun Omo ti ko gbon;
- Ekun nbe fun Omo ti o nsa kiri!
- Ma fi owurọ sere ore mi;
- Mura si isę ọjọ
nlọ!
|
|
|
|